1 Samuẹli 14:7
1 Samuel 14:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì wí pé, “Ṣe gbogbo ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ, tẹ̀síwájú, Èmi wà pẹ̀lú ọkàn àti ẹ̀mí rẹ.”
1 Samuel 14:7 in English
1 Samuel 14:7 · Berean Standard Bible
His armor-bearer replied, “Do all that is in your heart. Go ahead; I am with you heart and soul.”
Context
5Bèbè òkúta kan dúró sí àríwá ní ìhà Mikmasi, èkejì sì wà ní gúúsù ní ìhà Gibeah. 6Jonatani sì wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ sí ìlú olódi àwọn aláìkọlà yìí. Bóyá Olúwa yóò jà fún wa, kò sí ohun tó lè di Olúwa lọ́wọ́ láti gbàlà, yálà nípasẹ̀ púpọ̀ tàbí nípasẹ̀ díẹ̀.” 7Ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì wí pé, “Ṣe gbogbo ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ, tẹ̀síwájú, Èmi wà pẹ̀lú ọkàn àti ẹ̀mí rẹ.” 8Jonatani sì wí pé, “Wá nígbà náà, àwa yóò rékọjá sí ọ̀dọ̀ ọkùnrin wọ̀nyí, kí a sì jẹ́ kí wọ́n rí wa. 9Bí wọ́n bá sọ fún wa pé, ‘Ẹ dúró títí àwa yóò fi tọ̀ yín wá,’ àwa yóò dúró sí ibi tí a wà, àwa kì yóò sì gòkè tọ̀ wọ́n lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.