Native Bible

1 Samuel 14:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bèbè òkúta kan dúró sí àríwá ní ìhà Mikmasi, èkejì sì wà ní gúúsù ní ìhà Gibeah.

1 Samuel 14:5 in English

1 Samuel 14:5 · Berean Standard Bible

One cliff stood to the north toward Michmash, and the other to the south toward Geba.

Context

3lára wọn ni Ahijah, tí ó wọ efodu. Òun ni ọmọ arákùnrin Ikabodu Ahitubu, ọmọ Finehasi, ọmọ Eli, àlùfáà Olúwa ní Ṣilo kò sí ẹni tí ó mọ̀ pé Jonatani ti lọ. 4Ní ọ̀nà tí Jonatani ti ń fẹ́ láti kọjá dé ìlú olódi àwọn Filistini, ní bèbè òkúta mímú kan wá, orúkọ èkínní sì ń jẹ́ Bosesi, orúkọ èkejì sì ń jẹ́ Sene. 5Bèbè òkúta kan dúró sí àríwá ní ìhà Mikmasi, èkejì sì wà ní gúúsù ní ìhà Gibeah. 6Jonatani sì wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ sí ìlú olódi àwọn aláìkọlà yìí. Bóyá Olúwa yóò jà fún wa, kò sí ohun tó lè di Olúwa lọ́wọ́ láti gbàlà, yálà nípasẹ̀ púpọ̀ tàbí nípasẹ̀ díẹ̀.” 7Ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì wí pé, “Ṣe gbogbo ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ, tẹ̀síwájú, Èmi wà pẹ̀lú ọkàn àti ẹ̀mí rẹ.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.