1 Samuẹli 11:13
1 Samuel 11:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n Saulu wí pé, “A kì yóò pa ẹnikẹ́ni lónìí, nítorí lónìí yìí ni Olúwa ṣiṣẹ́ ìgbàlà ní Israẹli.”
1 Samuel 11:13 in English
1 Samuel 11:13 · Berean Standard Bible
But Saul ordered, “No one shall be put to death this day, for today the LORD has worked salvation in Israel.”
Context
11Ní ọjọ́ kejì Saulu pín àwọn ọkùnrin rẹ̀ sí ipa mẹ́ta, wọ́n sì ya wọ àgọ́ àwọn ará Ammoni ní ìṣọ́ òwúrọ̀, wọ́n sì pa wọ́n títí di ìmóoru ọjọ́. Àwọn tókù wọ́n sì fọ́nká, tó bẹ́ẹ̀ tí méjì wọn kò kù sí ibìkan. 12Àwọn ènìyàn sọ fún Samuẹli pé, “Ta ni ó béèrè wí pé, Saulu yóò ha jẹ ọba lórí wa? Mú àwọn ọkùnrin náà wá, a ó sì pa wọ́n.” 13Ṣùgbọ́n Saulu wí pé, “A kì yóò pa ẹnikẹ́ni lónìí, nítorí lónìí yìí ni Olúwa ṣiṣẹ́ ìgbàlà ní Israẹli.” 14Nígbà náà ni Samuẹli wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Gilgali, kí a lè fi ẹsẹ̀ Saulu múlẹ̀ bí ọba.” 15Nítorí náà gbogbo ènìyàn lọ sí Gilgali, wọn sí fi Saulu jẹ ọba ní iwájú Olúwa. Níbẹ̀, ni wọn ti rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ ní iwájú Olúwa, Saulu àti gbogbo Israẹli ṣe àjọyọ̀ ńlá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.