Native Bible

1 Samuel 10:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Samuẹli sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn pé, “Ṣé ẹ ti ri ọkùnrin tí Olúwa ti yàn? Kò sí ẹnìkan bí i rẹ̀ láàrín gbogbo àwọn ènìyàn.” Nígbà náà àwọn ènìyàn kígbe pé, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn!”

1 Samuel 10:24 in English

1 Samuel 10:24 · Berean Standard Bible

Samuel said to all the people, “Do you see the one the LORD has chosen? There is no one like him among all the people.” And all the people shouted, “Long live the king!”

Context

22bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Olúwa pé, “Ṣé ọkùnrin náà ti wá sí bí ni?” Olúwa sì sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ láàrín àwọn ẹrù.” 23Wọ́n sáré, wọ́n sì mú un jáde wá. Bí ó ti dúró láàrín àwọn ènìyàn, ó sì ga ju gbogbo àwọn tí ó kù lọ láti èjìká rẹ̀ sókè. 24Samuẹli sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn pé, “Ṣé ẹ ti ri ọkùnrin tí Olúwa ti yàn? Kò sí ẹnìkan bí i rẹ̀ láàrín gbogbo àwọn ènìyàn.” Nígbà náà àwọn ènìyàn kígbe pé, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn!” 25Samuẹli ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn àwọn ìlànà ìjọba. Ó kọ wọ́n sínú ìwé, ó sì fi lélẹ̀ níwájú Olúwa. Lẹ́yìn náà, Samuẹli tú àwọn ènìyàn ká olúkúlùkù sí ilé e rẹ̀. 26Saulu náà padà sí ilé e rẹ̀ ní Gibeah. Àwọn akọni ọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi ọwọ́ tọ́ ọkàn wọ́n sì sìn ín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.