1 Samuẹli 10:26
1 Samuel 10:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Saulu náà padà sí ilé e rẹ̀ ní Gibeah. Àwọn akọni ọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi ọwọ́ tọ́ ọkàn wọ́n sì sìn ín.
1 Samuel 10:26 in English
1 Samuel 10:26 · Berean Standard Bible
Saul also went to his home in Gibeah, and the men of valor whose hearts God had touched went with him.
Context
24Samuẹli sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn pé, “Ṣé ẹ ti ri ọkùnrin tí Olúwa ti yàn? Kò sí ẹnìkan bí i rẹ̀ láàrín gbogbo àwọn ènìyàn.”
Nígbà náà àwọn ènìyàn kígbe pé, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn!” 25Samuẹli ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn àwọn ìlànà ìjọba. Ó kọ wọ́n sínú ìwé, ó sì fi lélẹ̀ níwájú Olúwa. Lẹ́yìn náà, Samuẹli tú àwọn ènìyàn ká olúkúlùkù sí ilé e rẹ̀. 26Saulu náà padà sí ilé e rẹ̀ ní Gibeah. Àwọn akọni ọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi ọwọ́ tọ́ ọkàn wọ́n sì sìn ín. 27Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Beliali wí pé, “Báwo ni ọkùnrin yìí yóò ti ṣe gbà wá?” Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọn kò sì mú ẹ̀bùn wá fún un, ṣùgbọ́n Saulu fọwọ́ lérán.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.