Native Bible

1 Samuel 10:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó kó ẹ̀yà Benjamini síwájú ní ìdílé ìdílé, a sì yan ìdílé Matiri. Ní ìparí a sì yan Saulu ọmọ Kiṣi. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí wọ́n wá a, a kò rí i,

1 Samuel 10:21 in English

1 Samuel 10:21 · Berean Standard Bible

Then he had the tribe of Benjamin come forward by its clans, and the clan of Matri was selected.* Finally, Saul son of Kish was selected. But when they looked for him, they could not find him.

Context

19Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti kọ Ọlọ́run yín, tí ó gbà yín kúrò nínú gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú yín. Ẹ̀yin sì ti sọ pé, ‘Rárá, yan ọba kan fún wa.’ Báyìí, ẹ kó ara yín jọ níwájú Olúwa ní ẹ̀yà àti ìdílé yín.” 20Nígbà tí Samuẹli mú gbogbo ẹ̀yà Israẹli súnmọ́ tòsí, ó yan ẹ̀yà Benjamini. 21Ó kó ẹ̀yà Benjamini síwájú ní ìdílé ìdílé, a sì yan ìdílé Matiri. Ní ìparí a sì yan Saulu ọmọ Kiṣi. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí wọ́n wá a, a kò rí i, 22bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Olúwa pé, “Ṣé ọkùnrin náà ti wá sí bí ni?” Olúwa sì sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ láàrín àwọn ẹrù.” 23Wọ́n sáré, wọ́n sì mú un jáde wá. Bí ó ti dúró láàrín àwọn ènìyàn, ó sì ga ju gbogbo àwọn tí ó kù lọ láti èjìká rẹ̀ sókè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.