1 Samuẹli 1:24
1 Samuel 1:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ó sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, ó sì mú un gòkè lọ pẹ̀lú ara rẹ̀. Pẹ̀lú ẹgbọrọ màlúù mẹ́ta, àti ìyẹ̀fun efa kan, àti ìgò ọtí wáìnì kan, ó sì mú un wá sí ilé Olúwa ní Ṣilo: ọmọ náà sì wà ní ọmọdé.
1 Samuel 1:24 in English
1 Samuel 1:24 · Berean Standard Bible
Once she had weaned him, Hannah took the boy with her, along with a three-year-old bull,* an ephah of flour,* and a skin of wine. Though the boy was still young, she brought him to the house of the LORD at Shiloh.
Context
22Ṣùgbọ́n Hana kò gòkè lọ; nítorí tí ó sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Ó di ìgbà tí mo bá gba ọmú lẹ́nu ọmọ náà, nígbà náà ni èmi yóò mú un lọ, kí òun lè fi ara hàn níwájú Olúwa, kí ó sí máa gbé ibẹ̀ títí láé.” 23Elkana ọkọ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ. Dúró títí ìwọ yóò fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀; ṣùgbọ́n kí Olúwa sá à mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin náà sì jókòó, ó sì fi ọmú fún ọmọ rẹ̀ títí ó fi gbà á lẹ́nu rẹ̀. 24Nígbà tí ó sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, ó sì mú un gòkè lọ pẹ̀lú ara rẹ̀. Pẹ̀lú ẹgbọrọ màlúù mẹ́ta, àti ìyẹ̀fun efa kan, àti ìgò ọtí wáìnì kan, ó sì mú un wá sí ilé Olúwa ní Ṣilo: ọmọ náà sì wà ní ọmọdé. 25Wọ́n pa ẹgbọrọ màlúù, wọ́n sì mú ọmọ náà tọ Eli wá. 26Hana sì wí pé, “Olúwa mi, bí ọkàn rẹ ti wà láààyè, Olúwa mi, èmi ni obìnrin náà tí ó dúró lẹ́bàá ọ̀dọ̀ rẹ níhìn-ín tí ń tọrọ lọ́dọ̀ Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.