Native Bible

1 Kings 8:58 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ó fa ọkàn wa sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀, láti máa rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, àti àṣẹ rẹ̀, àti ìlànà rẹ̀, tí ó ti pàṣẹ fún àwọn baba wa.

1 Kings 8:58 in English

1 Kings 8:58 · Berean Standard Bible

May He incline our hearts to Himself, to walk in all His ways and to keep the commandments and statutes and ordinances He commanded our fathers.

Context

56“Ìbùkún ni fún Olúwa tí ó ti fi ìsinmi fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀ bí ó ti ṣèlérí. Kò sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ìlérí rere tí ó ti ṣe láti ọwọ́ Mose ìránṣẹ́ rẹ̀ wá. 57Kí Olúwa Ọlọ́run wa kí ó wà pẹ̀lú wa bí ó ti wà pẹ̀lú àwọn baba wa; kí ó má sì ṣe fi wá sílẹ̀ tàbí kọ̀ wá sílẹ̀. 58Kí ó fa ọkàn wa sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀, láti máa rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, àti àṣẹ rẹ̀, àti ìlànà rẹ̀, tí ó ti pàṣẹ fún àwọn baba wa. 59Àti kí ó sì jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí, tí mo ti gbà ní àdúrà níwájú Olúwa, kí ó wà nítòsí Olúwa Ọlọ́run wa ní ọ̀sán àti ní òru, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró àti ọ̀rọ̀ Israẹli ènìyàn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àìní wa ojoojúmọ́, 60kí gbogbo ènìyàn ayé lè mọ̀ pé Olúwa òun ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.