Native Bible

1 Kings 8:56 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ìbùkún ni fún Olúwa tí ó ti fi ìsinmi fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀ bí ó ti ṣèlérí. Kò sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ìlérí rere tí ó ti ṣe láti ọwọ́ Mose ìránṣẹ́ rẹ̀ wá.

1 Kings 8:56 in English

1 Kings 8:56 · Berean Standard Bible

“Blessed be the LORD, who has given rest to His people Israel according to all that He promised. Not one word has failed of all the good promises He made through His servant Moses.

Context

54Nígbà tí Solomoni ti parí gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ yìí sí Olúwa tán, ó dìde kúrò lórí eékún rẹ̀ níwájú pẹpẹ Olúwa níbi tí ó ti kúnlẹ̀ tí ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí òkè ọ̀run 55Ó sì dìde dúró ó sì fi ohùn rara súre fún gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli wí pé, 56“Ìbùkún ni fún Olúwa tí ó ti fi ìsinmi fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀ bí ó ti ṣèlérí. Kò sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ìlérí rere tí ó ti ṣe láti ọwọ́ Mose ìránṣẹ́ rẹ̀ wá. 57Kí Olúwa Ọlọ́run wa kí ó wà pẹ̀lú wa bí ó ti wà pẹ̀lú àwọn baba wa; kí ó má sì ṣe fi wá sílẹ̀ tàbí kọ̀ wá sílẹ̀. 58Kí ó fa ọkàn wa sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀, láti máa rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, àti àṣẹ rẹ̀, àti ìlànà rẹ̀, tí ó ti pàṣẹ fún àwọn baba wa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.