Native Bible

1 Kings 8:60 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

kí gbogbo ènìyàn ayé lè mọ̀ pé Olúwa òun ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn.

1 Kings 8:60 in English

1 Kings 8:60 · Berean Standard Bible

so that all the peoples of the earth may know that the LORD is God. There is no other!

Context

58Kí ó fa ọkàn wa sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀, láti máa rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, àti àṣẹ rẹ̀, àti ìlànà rẹ̀, tí ó ti pàṣẹ fún àwọn baba wa. 59Àti kí ó sì jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí, tí mo ti gbà ní àdúrà níwájú Olúwa, kí ó wà nítòsí Olúwa Ọlọ́run wa ní ọ̀sán àti ní òru, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró àti ọ̀rọ̀ Israẹli ènìyàn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àìní wa ojoojúmọ́, 60kí gbogbo ènìyàn ayé lè mọ̀ pé Olúwa òun ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn. 61Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí ọkàn yín pé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run wa, láti máa rìn nínú àṣẹ rẹ̀ àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, bí i ti òní yìí.” 62Nígbà náà ni ọba àti gbogbo Israẹli rú ẹbọ níwájú Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.