1 Ọba 8:41
1 Kings 8:41 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ní ti àwọn àlejò tí kì í ṣe Israẹli ènìyàn rẹ, ṣùgbọ́n tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè jáde wá nítorí orúkọ rẹ,
1 Kings 8:41 in English
1 Kings 8:41 · Berean Standard Bible
And as for the foreigner who is not of Your people Israel but has come from a distant land because of Your name—
Context
39nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ. Dáríjì, kí o sì ṣe sí olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó ti ṣe, níwọ̀n ìgbà tí ìwọ mọ ọkàn rẹ̀, nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni ó mọ ọkàn gbogbo ènìyàn. 40Nítorí wọn yóò bẹ̀rù rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọn yóò wà ní ilẹ̀ tí ìwọ fi fún àwọn baba wa. 41“Ní ti àwọn àlejò tí kì í ṣe Israẹli ènìyàn rẹ, ṣùgbọ́n tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè jáde wá nítorí orúkọ rẹ, 42nítorí tí àwọn ènìyàn yóò gbọ́ orúkọ ńlá rẹ, àti ọwọ́ agbára rẹ, àti nínà apá rẹ, nígbà tí ó bá sì wá, tí ó sì gbàdúrà sí ìhà ilé yìí, 43nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí àlejò náà yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ, kí gbogbo ènìyàn ní ayé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọn kí ó sì máa bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Israẹli, ènìyàn rẹ ti ṣe, kí wọn kí ó sì le mọ̀ pé orúkọ rẹ ni a fi pe ilé yìí tí mo kọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.