Native Bible

1 Kings 8:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ. Dáríjì, kí o sì ṣe sí olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó ti ṣe, níwọ̀n ìgbà tí ìwọ mọ ọkàn rẹ̀, nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni ó mọ ọkàn gbogbo ènìyàn.

1 Kings 8:39 in English

1 Kings 8:39 · Berean Standard Bible

be heard by You from heaven, Your dwelling place. And may You forgive and act, and repay each man according to all his ways, since You know his heart—for You alone know the hearts of all men—

Context

37“Nígbà tí ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn bá wá sí ilẹ̀ náà, tàbí ìrẹ̀dànù tàbí ìmúwòdù, eṣú tàbí kòkòrò tí ń jẹ ni run, tàbí nígbà tí àwọn ọ̀tá bá dó tì wọ́n nínú àwọn ìlú wọn, irú ìpọ́njú tàbí ààrùnkárùn tó lè wá, 38nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá ti ọ̀dọ̀ ẹnìkan láti ọ̀dọ̀ gbogbo Israẹli wá, tí olúkúlùkù sì mọ ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀, bí ó bá sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé yìí, 39nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ. Dáríjì, kí o sì ṣe sí olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó ti ṣe, níwọ̀n ìgbà tí ìwọ mọ ọkàn rẹ̀, nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni ó mọ ọkàn gbogbo ènìyàn. 40Nítorí wọn yóò bẹ̀rù rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọn yóò wà ní ilẹ̀ tí ìwọ fi fún àwọn baba wa. 41“Ní ti àwọn àlejò tí kì í ṣe Israẹli ènìyàn rẹ, ṣùgbọ́n tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè jáde wá nítorí orúkọ rẹ,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.