Native Bible

1 Kings 8:40 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí wọn yóò bẹ̀rù rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọn yóò wà ní ilẹ̀ tí ìwọ fi fún àwọn baba wa.

1 Kings 8:40 in English

1 Kings 8:40 · Berean Standard Bible

so that they may fear You all the days they live in the land that You gave to our fathers.

Context

38nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá ti ọ̀dọ̀ ẹnìkan láti ọ̀dọ̀ gbogbo Israẹli wá, tí olúkúlùkù sì mọ ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀, bí ó bá sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé yìí, 39nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ. Dáríjì, kí o sì ṣe sí olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó ti ṣe, níwọ̀n ìgbà tí ìwọ mọ ọkàn rẹ̀, nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni ó mọ ọkàn gbogbo ènìyàn. 40Nítorí wọn yóò bẹ̀rù rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọn yóò wà ní ilẹ̀ tí ìwọ fi fún àwọn baba wa. 41“Ní ti àwọn àlejò tí kì í ṣe Israẹli ènìyàn rẹ, ṣùgbọ́n tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè jáde wá nítorí orúkọ rẹ, 42nítorí tí àwọn ènìyàn yóò gbọ́ orúkọ ńlá rẹ, àti ọwọ́ agbára rẹ, àti nínà apá rẹ, nígbà tí ó bá sì wá, tí ó sì gbàdúrà sí ìhà ilé yìí,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.