1 Ọba 8:34
1 Kings 8:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli, ènìyàn rẹ̀ jì í, kí o sì mú wọn padà wá sí ilẹ̀ tí ìwọ ti fún àwọn baba wọn.
1 Kings 8:34 in English
1 Kings 8:34 · Berean Standard Bible
then may You hear from heaven and forgive the sin of Your people Israel. May You restore them to the land You gave to their fathers.
Context
32nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì ṣe. Kí o sì ṣèdájọ́ láàrín àwọn ìránṣẹ́ rẹ, dá ènìyàn búburú lẹ́bi, kí o sì mú wá sí orí òun tìkára rẹ̀ ohun tí ó ti ṣe, dá olóòtítọ́ láre, kí a sì fi ẹsẹ̀ àìlẹ́bi rẹ̀ múlẹ̀. 33“Nígbà tí àwọn ọ̀tá bá ṣẹ́gun Israẹli, ènìyàn rẹ, nítorí tí wọ́n ti ṣẹ̀ sí ọ, tí wọ́n bá yípadà sí ọ, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ nínú ilé yìí 34nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli, ènìyàn rẹ̀ jì í, kí o sì mú wọn padà wá sí ilẹ̀ tí ìwọ ti fún àwọn baba wọn. 35“Nígbà tí ọ̀run bá sé mọ́, tí kò sí òjò, nítorí tí àwọn ènìyàn rẹ ti ṣẹ̀ sí ọ, bí wọ́n bá gbàdúrà sí ìhà ibí yìí, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí tí ìwọ ti pọ́n wọn lójú, 36nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ jì wọ́n, à ní Israẹli, ènìyàn rẹ. Kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ láti máa rìn, kí o sì rọ òjò sí ilẹ̀ tí ìwọ ti fi fún ènìyàn rẹ fún ìní.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.