Native Bible

1 Kings 8:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ jì wọ́n, à ní Israẹli, ènìyàn rẹ. Kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ láti máa rìn, kí o sì rọ òjò sí ilẹ̀ tí ìwọ ti fi fún ènìyàn rẹ fún ìní.

1 Kings 8:36 in English

1 Kings 8:36 · Berean Standard Bible

then may You hear from heaven and forgive the sin of Your servants, Your people Israel, so that You may teach them the good way in which they should walk. May You send rain on the land that You gave Your people as an inheritance.

Context

34nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli, ènìyàn rẹ̀ jì í, kí o sì mú wọn padà wá sí ilẹ̀ tí ìwọ ti fún àwọn baba wọn. 35“Nígbà tí ọ̀run bá sé mọ́, tí kò sí òjò, nítorí tí àwọn ènìyàn rẹ ti ṣẹ̀ sí ọ, bí wọ́n bá gbàdúrà sí ìhà ibí yìí, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí tí ìwọ ti pọ́n wọn lójú, 36nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ jì wọ́n, à ní Israẹli, ènìyàn rẹ. Kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ láti máa rìn, kí o sì rọ òjò sí ilẹ̀ tí ìwọ ti fi fún ènìyàn rẹ fún ìní. 37“Nígbà tí ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn bá wá sí ilẹ̀ náà, tàbí ìrẹ̀dànù tàbí ìmúwòdù, eṣú tàbí kòkòrò tí ń jẹ ni run, tàbí nígbà tí àwọn ọ̀tá bá dó tì wọ́n nínú àwọn ìlú wọn, irú ìpọ́njú tàbí ààrùnkárùn tó lè wá, 38nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá ti ọ̀dọ̀ ẹnìkan láti ọ̀dọ̀ gbogbo Israẹli wá, tí olúkúlùkù sì mọ ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀, bí ó bá sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé yìí,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.