1 Ọba 8:24
1 Kings 8:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
O sì ti pa ìlérí rẹ mọ́ fún ìránṣẹ́ rẹ Dafidi baba mi; pẹ̀lú ẹnu rẹ ni ìwọ ṣe ìlérí, o sì mú u ṣẹ pẹ̀lú ọwọ́ rẹ, bí ó ti rí lónìí.
1 Kings 8:24 in English
1 Kings 8:24 · Berean Standard Bible
You have kept Your promise to Your servant, my father David. What You spoke with Your mouth You have fulfilled with Your hand this day.
Context
22Solomoni sì dúró níwájú pẹpẹ Olúwa, níwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sókè ọ̀run. 23Ó sì wí pé,
“Olúwa Ọlọ́run Israẹli, kò sí Ọlọ́run tí ó dàbí rẹ lókè ọ̀run tàbí ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ìwọ tí ó pa májẹ̀mú àti àánú mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ń fi gbogbo ọkàn wọn rìn níwájú rẹ. 24O sì ti pa ìlérí rẹ mọ́ fún ìránṣẹ́ rẹ Dafidi baba mi; pẹ̀lú ẹnu rẹ ni ìwọ ṣe ìlérí, o sì mú u ṣẹ pẹ̀lú ọwọ́ rẹ, bí ó ti rí lónìí. 25“Ǹjẹ́ báyìí Olúwa Ọlọ́run Israẹli, bá ìránṣẹ́ rẹ̀ Dafidi baba mi pa ohun tí ìwọ ti ṣe ìlérí fún un mọ́ wí pé, ìwọ kì yóò kùnà láti ní ènìyàn kan láti jókòó níwájú mi lórí ìtẹ́ Israẹli, kìkì bí àwọn ọmọ rẹ bá lè kíyèsi ohun tí wọ́n ń ṣe láti máa rìn níwájú mi bí ìwọ ti rìn. 26Ǹjẹ́ báyìí, Ọlọ́run Israẹli, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tí o ti ṣe ìlérí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Dafidi baba mi wá sí ìmúṣẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.