Native Bible

1 Kings 8:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì wí pé, “Olúwa Ọlọ́run Israẹli, kò sí Ọlọ́run tí ó dàbí rẹ lókè ọ̀run tàbí ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ìwọ tí ó pa májẹ̀mú àti àánú mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ń fi gbogbo ọkàn wọn rìn níwájú rẹ.

1 Kings 8:23 in English

1 Kings 8:23 · Berean Standard Bible

and said: “O LORD, God of Israel, there is no God like You in heaven above or on earth below, keeping Your covenant of loving devotion with Your servants who walk before You with all their hearts.

Context

21Èmi sì ti pèsè ibìkan níbẹ̀ fún àpótí ẹ̀rí, èyí tí í ṣe májẹ̀mú Olúwa tí ó ti bá àwọn baba wa dá, nígbà tí ó mú wọn jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá.” 22Solomoni sì dúró níwájú pẹpẹ Olúwa, níwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sókè ọ̀run. 23Ó sì wí pé, “Olúwa Ọlọ́run Israẹli, kò sí Ọlọ́run tí ó dàbí rẹ lókè ọ̀run tàbí ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ìwọ tí ó pa májẹ̀mú àti àánú mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ń fi gbogbo ọkàn wọn rìn níwájú rẹ. 24O sì ti pa ìlérí rẹ mọ́ fún ìránṣẹ́ rẹ Dafidi baba mi; pẹ̀lú ẹnu rẹ ni ìwọ ṣe ìlérí, o sì mú u ṣẹ pẹ̀lú ọwọ́ rẹ, bí ó ti rí lónìí. 25“Ǹjẹ́ báyìí Olúwa Ọlọ́run Israẹli, bá ìránṣẹ́ rẹ̀ Dafidi baba mi pa ohun tí ìwọ ti ṣe ìlérí fún un mọ́ wí pé, ìwọ kì yóò kùnà láti ní ènìyàn kan láti jókòó níwájú mi lórí ìtẹ́ Israẹli, kìkì bí àwọn ọmọ rẹ bá lè kíyèsi ohun tí wọ́n ń ṣe láti máa rìn níwájú mi bí ìwọ ti rìn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.