1 Ọba 8:26
1 Kings 8:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ báyìí, Ọlọ́run Israẹli, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tí o ti ṣe ìlérí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Dafidi baba mi wá sí ìmúṣẹ.
1 Kings 8:26 in English
1 Kings 8:26 · Berean Standard Bible
And now, O God of Israel, please confirm what You promised to Your servant, my father David.
Context
24O sì ti pa ìlérí rẹ mọ́ fún ìránṣẹ́ rẹ Dafidi baba mi; pẹ̀lú ẹnu rẹ ni ìwọ ṣe ìlérí, o sì mú u ṣẹ pẹ̀lú ọwọ́ rẹ, bí ó ti rí lónìí. 25“Ǹjẹ́ báyìí Olúwa Ọlọ́run Israẹli, bá ìránṣẹ́ rẹ̀ Dafidi baba mi pa ohun tí ìwọ ti ṣe ìlérí fún un mọ́ wí pé, ìwọ kì yóò kùnà láti ní ènìyàn kan láti jókòó níwájú mi lórí ìtẹ́ Israẹli, kìkì bí àwọn ọmọ rẹ bá lè kíyèsi ohun tí wọ́n ń ṣe láti máa rìn níwájú mi bí ìwọ ti rìn. 26Ǹjẹ́ báyìí, Ọlọ́run Israẹli, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tí o ti ṣe ìlérí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Dafidi baba mi wá sí ìmúṣẹ. 27“Ṣùgbọ́n nítòótọ́, Ọlọ́run yóò máa gbé ayé bí? Ọ̀run àti ọ̀run àwọn ọ̀run kò le gbà ọ́. Kí a má sọ pé ilé yìí tí mo kọ́ fún ọ! 28Síbẹ̀ ṣe ìfetísílẹ̀ àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ fún àánú, Olúwa Ọlọ́run mi. Gbọ́ ẹkún àti àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ń gbà níwájú rẹ lónìí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.