Native Bible

1 Kings 7:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Báyìí ni a sì ṣe ẹsẹ̀ náà, wọ́n ní àlàfo ọnà àárín tí a so mọ́ agbede-méjì ìpàdé etí.

1 Kings 7:28 in English

1 Kings 7:28 · Berean Standard Bible

This was the design of the stands: They had side panels attached to uprights,

Context

26Ó sì nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ sì dàbí etí ago, bí ìtànná lílì. Ó sì gba ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìwọ̀n bati. 27Ó sì túnṣe ẹsẹ̀ idẹ tí a lè gbé mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gígùn, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní ìbú àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gíga. 28Báyìí ni a sì ṣe ẹsẹ̀ náà, wọ́n ní àlàfo ọnà àárín tí a so mọ́ agbede-méjì ìpàdé etí. 29Lórí àlàfo ọnà àárín tí ó wà lágbedeméjì ni àwòrán kìnnìún, màlúù, àti àwọn kérúbù wà, àti lórí ìpàdé etí bákan náà. Lókè àti nísàlẹ̀ àwọn kìnnìún, màlúù sì ni iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ wà. 30Ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan sì ni kẹ̀kẹ́ idẹ mẹ́rin pẹ̀lú ọ̀pá kẹ̀kẹ́ idẹ, ọ̀kọ̀ọ̀kan ni ó ní ìfẹsẹ̀tẹ̀ lábẹ́, tí a gbẹ́, iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ wà ní ìhà gbogbo rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.