1 Ọba 7:30
1 Kings 7:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan sì ni kẹ̀kẹ́ idẹ mẹ́rin pẹ̀lú ọ̀pá kẹ̀kẹ́ idẹ, ọ̀kọ̀ọ̀kan ni ó ní ìfẹsẹ̀tẹ̀ lábẹ́, tí a gbẹ́, iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ wà ní ìhà gbogbo rẹ̀.
1 Kings 7:30 in English
1 Kings 7:30 · Berean Standard Bible
Each stand had four bronze wheels with bronze axles and a basin resting on four supports, with wreaths at each side.
Context
28Báyìí ni a sì ṣe ẹsẹ̀ náà, wọ́n ní àlàfo ọnà àárín tí a so mọ́ agbede-méjì ìpàdé etí. 29Lórí àlàfo ọnà àárín tí ó wà lágbedeméjì ni àwòrán kìnnìún, màlúù, àti àwọn kérúbù wà, àti lórí ìpàdé etí bákan náà. Lókè àti nísàlẹ̀ àwọn kìnnìún, màlúù sì ni iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ wà. 30Ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan sì ni kẹ̀kẹ́ idẹ mẹ́rin pẹ̀lú ọ̀pá kẹ̀kẹ́ idẹ, ọ̀kọ̀ọ̀kan ni ó ní ìfẹsẹ̀tẹ̀ lábẹ́, tí a gbẹ́, iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ wà ní ìhà gbogbo rẹ̀. 31Nínú ẹsẹ̀ náà ẹnu kan wà tí ó kọ bíríkítí tí ó jìn ní ìgbọ̀nwọ́ kan. Ẹnu yìí ṣe róbótó àti pẹ̀lú iṣẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀. Ní àyíká ẹnu rẹ̀ ni ohun ọnà gbígbẹ́ wà. Àlàfo ọ̀nà àárín ẹsẹ̀ náà sì ní igun mẹ́rin, wọn kò yíká. 32Kẹ̀kẹ́ mẹ́rin sì wà nísàlẹ̀ àlàfo ọ̀nà àárín, a sì so ọ̀pá àyíká kẹ̀kẹ́ náà mọ́ ẹsẹ̀ náà. Gíga àyíká kẹ̀kẹ́ kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.