Native Bible

1 Kings 4:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Oúnjẹ Solomoni fún ọjọ́ kan jásí ọgbọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná àti ọgọ́ta òsùwọ̀n ìyẹ̀fun,

1 Kings 4:22 in English

1 Kings 4:22 · Berean Standard Bible

Solomon’s provisions for a single day were thirty cors of fine flour,* sixty cors of meal,*

Context

20Àwọn ènìyàn Juda àti ti Israẹli pọ̀ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn tí ń bẹ ní etí Òkun; wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, wọ́n sì ń yọ ayọ̀. 21Solomoni sì ń ṣàkóso lórí gbogbo àwọn ìjọba láti odò Eufurate títí dé ilẹ̀ àwọn ará Filistini, àti títí dé etí ilẹ̀ Ejibiti. Àwọn orílẹ̀-èdè yìí ń mú owó òde wá, wọ́n sì ń sin Solomoni ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. 22Oúnjẹ Solomoni fún ọjọ́ kan jásí ọgbọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná àti ọgọ́ta òsùwọ̀n ìyẹ̀fun, 23Màlúù mẹ́wàá tí ó sanra, àti ogún màlúù láti inú pápá wá, àti ọgọ́rùn-ún àgùntàn àti ewúrẹ́, láìka àgbọ̀nrín àti èsúró, àti ogbúgbu, àti ẹyẹ tí ó sanra. 24Nítorí òun ni ó ṣàkóso lórí gbogbo agbègbè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn odò Eufurate, láti Tifisa títí dé Gasa, lórí gbogbo àwọn ọba ní ìhà ìhín odò, ó sì ní àlàáfíà ní gbogbo ìlú tí ó yí i káàkiri.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.