Native Bible

1 Kings 21:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jesebeli aya rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí inú rẹ fi bàjẹ́, èéṣe tí ìwọ kò sì jẹun?”

1 Kings 21:5 in English

1 Kings 21:5 · Berean Standard Bible

Soon his wife Jezebel came in and asked, “Why are you so sullen that you refuse to eat?”

Context

3Ṣùgbọ́n Naboti wí fún Ahabu pé, “Olúwa má jẹ́ kí èmi fi ogún àwọn baba mi fún ọ.” 4Ahabu sì wá sí ilé rẹ̀, ó wugbọ́, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí ọ̀rọ̀ tí Naboti ará Jesreeli sọ fún un; nítorí tí ó wí pé, “Èmi kì yóò fún ọ ní ogún àwọn baba mi.” Ó sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀, ó sì yí ojú rẹ̀ padà, kò sì fẹ́ jẹun. 5Jesebeli aya rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí inú rẹ fi bàjẹ́, èéṣe tí ìwọ kò sì jẹun?” 6Ó sì dá a lóhùn pé, “Nítorí tí mo wí fún Naboti ará Jesreeli pé, ‘Ta ọgbà àjàrà rẹ fún mi, tàbí bí ó bá wù ọ́, èmi yóò fún ọ ní ọgbà àjàrà mìíràn ní ipò rẹ̀.’ Ṣùgbọ́n ó wí pé, ‘Èmi kì yóò fún ọ ní ọgbà àjàrà mi.’ ” 7Jesebeli aya rẹ̀ sì wí pé, “Ṣé báyìí ni ìwọ yóò ṣe ṣe bí ọba lórí Israẹli? Dìde, jẹun! Kí o sì jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn. Èmi yóò sì fún ọ ní ọgbà àjàrà Naboti ará Jesreeli.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.