1 Ọba 21:7
1 Kings 21:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jesebeli aya rẹ̀ sì wí pé, “Ṣé báyìí ni ìwọ yóò ṣe ṣe bí ọba lórí Israẹli? Dìde, jẹun! Kí o sì jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn. Èmi yóò sì fún ọ ní ọgbà àjàrà Naboti ará Jesreeli.”
1 Kings 21:7 in English
1 Kings 21:7 · Berean Standard Bible
But his wife Jezebel said to him, “Do you not reign over Israel? Get up, eat some food, and be cheerful, for I will get you the vineyard of Naboth the Jezreelite.”
Context
5Jesebeli aya rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí inú rẹ fi bàjẹ́, èéṣe tí ìwọ kò sì jẹun?” 6Ó sì dá a lóhùn pé, “Nítorí tí mo wí fún Naboti ará Jesreeli pé, ‘Ta ọgbà àjàrà rẹ fún mi, tàbí bí ó bá wù ọ́, èmi yóò fún ọ ní ọgbà àjàrà mìíràn ní ipò rẹ̀.’ Ṣùgbọ́n ó wí pé, ‘Èmi kì yóò fún ọ ní ọgbà àjàrà mi.’ ” 7Jesebeli aya rẹ̀ sì wí pé, “Ṣé báyìí ni ìwọ yóò ṣe ṣe bí ọba lórí Israẹli? Dìde, jẹun! Kí o sì jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn. Èmi yóò sì fún ọ ní ọgbà àjàrà Naboti ará Jesreeli.” 8Bẹ́ẹ̀ ni ó kọ̀wé ní orúkọ Ahabu, ó sì fi èdìdì rẹ̀ dì í, ó sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí àwọn àgbàgbà àti àwọn ọlọ́lá tí ó ń gbé ní ìlú Naboti pẹ̀lú rẹ̀. 9Nínú àwọn ìwé náà, ó kọ pé,
“Ẹ kéde àwẹ̀, kí ẹ sì fi Naboti sí ipò ọlá láàrín àwọn ènìyàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.