Native Bible

1 Kings 21:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ pàdé Ahabu ọba Israẹli, tí ó wà ní Samaria. Ó wà ní ọgbà àjàrà Naboti báyìí, níbi tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ láti jogún rẹ̀.

1 Kings 21:18 in English

1 Kings 21:18 · Berean Standard Bible

“Get up and go down to meet Ahab king of Israel, who is in Samaria. See, he is in the vineyard of Naboth, of which he has gone to take possession.

Context

16Nígbà tí Ahabu sì gbọ́ pé Naboti ti kú, ó sì dìde, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ láti jogún ọgbà àjàrà Naboti. 17Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Elijah ará Tiṣibi wá wí pé, 18“Sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ pàdé Ahabu ọba Israẹli, tí ó wà ní Samaria. Ó wà ní ọgbà àjàrà Naboti báyìí, níbi tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ láti jogún rẹ̀. 19Sọ fún un pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ǹjẹ́ ìwọ kò ti pa ènìyàn, o sì ti fi agbára gba ogún rẹ̀?’ Nígbà náà ni kí o wí fún un pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Níbi tí ajá gbé lá ẹ̀jẹ̀ Naboti, ni àwọn ajá yóò lá ẹ̀jẹ̀ rẹ, àní tìrẹ!’ ” 20Ahabu sì wí fún Elijah pé, “Ìwọ ti rí mi, ìwọ ọ̀tá mi!” Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti rí ọ, nítorí tí ìwọ ti tan ara rẹ láti ṣe búburú níwájú Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.