1 Ọba 21:20
1 Kings 21:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ahabu sì wí fún Elijah pé, “Ìwọ ti rí mi, ìwọ ọ̀tá mi!” Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti rí ọ, nítorí tí ìwọ ti tan ara rẹ láti ṣe búburú níwájú Olúwa.
1 Kings 21:20 in English
1 Kings 21:20 · Berean Standard Bible
When Elijah arrived, Ahab said to him, “So you have found me out, my enemy.” He replied, “I have found you out because you have sold yourself to do evil in the sight of the LORD.
Context
18“Sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ pàdé Ahabu ọba Israẹli, tí ó wà ní Samaria. Ó wà ní ọgbà àjàrà Naboti báyìí, níbi tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ láti jogún rẹ̀. 19Sọ fún un pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ǹjẹ́ ìwọ kò ti pa ènìyàn, o sì ti fi agbára gba ogún rẹ̀?’ Nígbà náà ni kí o wí fún un pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Níbi tí ajá gbé lá ẹ̀jẹ̀ Naboti, ni àwọn ajá yóò lá ẹ̀jẹ̀ rẹ, àní tìrẹ!’ ” 20Ahabu sì wí fún Elijah pé, “Ìwọ ti rí mi, ìwọ ọ̀tá mi!”
Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti rí ọ, nítorí tí ìwọ ti tan ara rẹ láti ṣe búburú níwájú Olúwa. 21‘Èmi yóò mú ibi wá sórí rẹ. Èmi yóò sì mú ìran rẹ kúrò, èmi yóò sì ké kúrò lọ́dọ̀ Ahabu gbogbo ọmọdé ọkùnrin, àti ọmọ ọ̀dọ̀, àti òmìnira ní Israẹli. 22Èmi yóò ṣe ilé rẹ bí ilé Jeroboamu, ọmọ Nebati, àti bí ilé Baaṣa, ọmọ Ahijah, nítorí ìwọ ti mú mi bínú, ìwọ sì ti mú Israẹli ṣẹ̀.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.