Native Bible

1 Kings 20:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn oníṣẹ́ náà sì tún padà wá, wọ́n sì wí pé, “Báyìí ni Beni-Hadadi sọ wí pé, ‘Mo ránṣẹ́ láti béèrè fún fàdákà rẹ àti wúrà rẹ, àwọn aya rẹ àti àwọn ọmọ rẹ.

1 Kings 20:5 in English

1 Kings 20:5 · Berean Standard Bible

The messengers came back and said, “This is what Ben-hadad says: ‘I have sent to you to demand your silver, your gold, your wives, and your children.

Context

3‘Fàdákà àti wúrà rẹ tèmi ni, àti àwọn tí ó dára jùlọ nínú àwọn aya rẹ àti àwọn ọmọ rẹ tèmi ni wọ́n.’ ” 4Ọba Israẹli sì dá a lóhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ṣe wí olúwa mi ọba, èmi àti ohun gbogbo tí mo ní tìrẹ ni.” 5Àwọn oníṣẹ́ náà sì tún padà wá, wọ́n sì wí pé, “Báyìí ni Beni-Hadadi sọ wí pé, ‘Mo ránṣẹ́ láti béèrè fún fàdákà rẹ àti wúrà rẹ, àwọn aya rẹ àti àwọn ọmọ rẹ. 6Ṣùgbọ́n ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò rán àwọn ìránṣẹ́ mi sí ọ láti wá ilé rẹ wò àti ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ. Wọn yóò gba gbogbo ohun tí ó bá dára lójú rẹ, wọn yóò sì kó o lọ.’ ” 7Nígbà náà ni ọba Israẹli pe gbogbo àwọn àgbàgbà ìlú, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wo bí ọkùnrin yìí ti ń fẹ́ ìyọnu! Nígbà tí ó ránṣẹ́ fún àwọn aya mi, àti fún àwọn ọmọ mi, àti fún fàdákà mi, àti fún wúrà mi, èmi kò sì fi dù ú.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.