1 Ọba 20:3
1 Kings 20:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
‘Fàdákà àti wúrà rẹ tèmi ni, àti àwọn tí ó dára jùlọ nínú àwọn aya rẹ àti àwọn ọmọ rẹ tèmi ni wọ́n.’ ”
1 Kings 20:3 in English
1 Kings 20:3 · Berean Standard Bible
saying, “This is what Ben-hadad says:* ‘Your silver and gold are mine, and your best wives and children are mine!’”
Context
1Beni-Hadadi ọba Aramu sì gbá gbogbo ogun rẹ̀ jọ. Ọba méjìlélọ́gbọ̀n sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ àti ẹṣin àti kẹ̀kẹ́, ó sì gòkè lọ, ó sì dó ti Samaria, ó sì kọlù ú. 2Ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí ìlú sí Ahabu ọba Israẹli wí pé, “Báyìí ni Beni-Hadadi wí, 3‘Fàdákà àti wúrà rẹ tèmi ni, àti àwọn tí ó dára jùlọ nínú àwọn aya rẹ àti àwọn ọmọ rẹ tèmi ni wọ́n.’ ” 4Ọba Israẹli sì dá a lóhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ṣe wí olúwa mi ọba, èmi àti ohun gbogbo tí mo ní tìrẹ ni.” 5Àwọn oníṣẹ́ náà sì tún padà wá, wọ́n sì wí pé, “Báyìí ni Beni-Hadadi sọ wí pé, ‘Mo ránṣẹ́ láti béèrè fún fàdákà rẹ àti wúrà rẹ, àwọn aya rẹ àti àwọn ọmọ rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.