Native Bible

1 Kings 2:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ̀síwájú pé, “Mo bẹ̀ ọ́, jọ̀wọ́ sọ fún Solomoni ọba (òun kì yóò kọ̀ fún ọ́) kí ó fún mi ní Abiṣagi ará Ṣunemu ní aya.”

1 Kings 2:17 in English

1 Kings 2:17 · Berean Standard Bible

Adonijah replied, “Please speak to King Solomon, since he will not turn you down. Let him give me Abishag the Shunammite as my wife.”

Context

15Ó wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀, ti tèmi ni ìjọba náà. Gbogbo Israẹli ti wò mí bí ọba wọn. Ṣùgbọ́n nǹkan yípadà, ìjọba náà sì ti lọ sí ọ̀dọ̀ arákùnrin mi, nítorí ó ti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọwọ́ Olúwa wá. 16Nísinsin yìí mo ní ìbéèrè kan láti bi ọ́, má ṣe kọ̀ fún mi.” Ó wí pé, “O lè wí.” 17Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ̀síwájú pé, “Mo bẹ̀ ọ́, jọ̀wọ́ sọ fún Solomoni ọba (òun kì yóò kọ̀ fún ọ́) kí ó fún mi ní Abiṣagi ará Ṣunemu ní aya.” 18Batṣeba sì dáhùn pé, “Ó dára èmi yóò bá ọba sọ̀rọ̀ nítorí rẹ̀.” 19Nígbà tí Batṣeba sì tọ Solomoni ọba lọ láti bá a sọ̀rọ̀ nítorí Adonijah, ọba sì dìde láti pàdé rẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó sì tẹ́ ìtẹ́ kan fún ìyá ọba, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.