Native Bible

1 Kings 2:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Batṣeba sì tọ Solomoni ọba lọ láti bá a sọ̀rọ̀ nítorí Adonijah, ọba sì dìde láti pàdé rẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó sì tẹ́ ìtẹ́ kan fún ìyá ọba, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀.

1 Kings 2:19 in English

1 Kings 2:19 · Berean Standard Bible

So Bathsheba went to King Solomon to speak to him for Adonijah. The king stood up to greet her, bowed to her, and sat down on his throne. Then the king had a throne brought for his mother, who sat down at his right hand.

Context

17Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ̀síwájú pé, “Mo bẹ̀ ọ́, jọ̀wọ́ sọ fún Solomoni ọba (òun kì yóò kọ̀ fún ọ́) kí ó fún mi ní Abiṣagi ará Ṣunemu ní aya.” 18Batṣeba sì dáhùn pé, “Ó dára èmi yóò bá ọba sọ̀rọ̀ nítorí rẹ̀.” 19Nígbà tí Batṣeba sì tọ Solomoni ọba lọ láti bá a sọ̀rọ̀ nítorí Adonijah, ọba sì dìde láti pàdé rẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó sì tẹ́ ìtẹ́ kan fún ìyá ọba, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀. 20Ó sì wí pé, “Mo ní ìbéèrè kékeré kan láti béèrè lọ́wọ́ rẹ, má ṣe kọ̀ fún mi.” Ọba sì dáhùn wí pé, “Béèrè, ìyá mi; èmi kì yóò kọ̀ ọ́.” 21Nígbà náà ni ó wí pé, “Jẹ́ kí a fi Abiṣagi ará Ṣunemu fún Adonijah arákùnrin rẹ ní aya.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.