1 Ọba 13:30
1 Kings 13:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni ó gbé òkú náà sínú ibojì ara rẹ̀, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ó ṣe, arákùnrin mi!”
1 Kings 13:30 in English
1 Kings 13:30 · Berean Standard Bible
Then he laid the body in his own tomb, and they lamented over him, “Oh, my brother!”
Context
28Nígbà náà ni ó sì jáde lọ, ó sì rí òkú náà tí a gbé sọ sí ojú ọ̀nà, pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kìnnìún náà kò sì jẹ òkú náà, tàbí fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ya. 29Nígbà náà ni wòlíì náà gbé òkú ènìyàn Ọlọ́run náà, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì gbé e padà wá sí ìlú ara rẹ̀ láti ṣọ̀fọ̀ fún un àti láti sin ín. 30Nígbà náà ni ó gbé òkú náà sínú ibojì ara rẹ̀, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ó ṣe, arákùnrin mi!” 31Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti sìnkú rẹ̀ tán, ó sì wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Nígbà tí mo bá kú, ẹ sin mí ní ibojì níbi tí a sin ènìyàn Ọlọ́run sí; ẹ tẹ́ egungun mi lẹ́bàá egungun rẹ̀. 32Nítorí iṣẹ́ tí ó jẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Olúwa sí pẹpẹ tí ó wà ní Beteli àti sí gbogbo ojúbọ lórí ibi gíga tí ń bẹ ní àwọn ìlú Samaria yóò wá sí ìmúṣẹ dájúdájú.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.