1 Ọba 13:28
1 Kings 13:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni ó sì jáde lọ, ó sì rí òkú náà tí a gbé sọ sí ojú ọ̀nà, pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kìnnìún náà kò sì jẹ òkú náà, tàbí fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ya.
1 Kings 13:28 in English
1 Kings 13:28 · Berean Standard Bible
and he went and found the body lying in the road, with the donkey and the lion standing beside it. The lion had not eaten the body or mauled the donkey.
Context
26Nígbà tí wòlíì tí ó mú un padà wá láti ọ̀nà rẹ̀ sì gbọ́ èyí, ó sì wí pé, “Ènìyàn Ọlọ́run náà ni tí ó ba ọ̀rọ̀ Olúwa jẹ́. Olúwa sì ti fi lé kìnnìún lọ́wọ́, tí ó sì fà á ya, tí ó sì pa á, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti kìlọ̀ fún un.” 27Wòlíì náà sì wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi,” wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. 28Nígbà náà ni ó sì jáde lọ, ó sì rí òkú náà tí a gbé sọ sí ojú ọ̀nà, pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kìnnìún náà kò sì jẹ òkú náà, tàbí fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ya. 29Nígbà náà ni wòlíì náà gbé òkú ènìyàn Ọlọ́run náà, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì gbé e padà wá sí ìlú ara rẹ̀ láti ṣọ̀fọ̀ fún un àti láti sin ín. 30Nígbà náà ni ó gbé òkú náà sínú ibojì ara rẹ̀, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ó ṣe, arákùnrin mi!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.