1 Ọba 13:29
1 Kings 13:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni wòlíì náà gbé òkú ènìyàn Ọlọ́run náà, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì gbé e padà wá sí ìlú ara rẹ̀ láti ṣọ̀fọ̀ fún un àti láti sin ín.
1 Kings 13:29 in English
1 Kings 13:29 · Berean Standard Bible
So the old prophet lifted up the body of the man of God, laid it on the donkey, and brought it back to his own city to mourn for him and bury him.
Context
27Wòlíì náà sì wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi,” wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. 28Nígbà náà ni ó sì jáde lọ, ó sì rí òkú náà tí a gbé sọ sí ojú ọ̀nà, pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kìnnìún náà kò sì jẹ òkú náà, tàbí fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ya. 29Nígbà náà ni wòlíì náà gbé òkú ènìyàn Ọlọ́run náà, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì gbé e padà wá sí ìlú ara rẹ̀ láti ṣọ̀fọ̀ fún un àti láti sin ín. 30Nígbà náà ni ó gbé òkú náà sínú ibojì ara rẹ̀, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ó ṣe, arákùnrin mi!” 31Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti sìnkú rẹ̀ tán, ó sì wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Nígbà tí mo bá kú, ẹ sin mí ní ibojì níbi tí a sin ènìyàn Ọlọ́run sí; ẹ tẹ́ egungun mi lẹ́bàá egungun rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.