1 Ọba 12:30
1 Kings 12:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nǹkan yìí sì di ẹ̀ṣẹ̀; àwọn ènìyàn sì lọ títí dé Dani láti sin èyí tí ó wà níbẹ̀.
1 Kings 12:30 in English
1 Kings 12:30 · Berean Standard Bible
And this thing became a sin; the people walked as far as Dan to worship before one of the calves.*
Context
28Lẹ́yìn tí ó ti gba ìmọ̀ràn, ọba sì yá ẹgbọrọ màlúù wúrà méjì. Ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ó ti pọ̀jù fún yín láti máa gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Àwọn Ọlọ́run yín nìyìí, Israẹli, tí ó mú yín láti ilẹ̀ Ejibiti wá.” 29Ó sì gbé ọ̀kan kalẹ̀ ní Beteli, àti èkejì ní Dani. 30Nǹkan yìí sì di ẹ̀ṣẹ̀; àwọn ènìyàn sì lọ títí dé Dani láti sin èyí tí ó wà níbẹ̀. 31Jeroboamu sì kọ́ ojúbọ sórí ibi gíga, ó sì yan àwọn àlùfáà láti inú àwọn ènìyàn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe inú àwọn ọmọ Lefi. 32Jeroboamu sì dá àsè sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kẹjọ gẹ́gẹ́ bí àsè tí ó wà ní Juda, ó sì rú ẹbọ lórí pẹpẹ. Ó ṣe èyí ní Beteli, ó rú ẹbọ sí àwọn ọmọ màlúù tí ó ṣe. Ó sì fi àwọn àlùfáà sí ibi gíga tí ó ti ṣe sí Beteli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.