Native Bible

1 Kings 12:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jeroboamu sì dá àsè sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kẹjọ gẹ́gẹ́ bí àsè tí ó wà ní Juda, ó sì rú ẹbọ lórí pẹpẹ. Ó ṣe èyí ní Beteli, ó rú ẹbọ sí àwọn ọmọ màlúù tí ó ṣe. Ó sì fi àwọn àlùfáà sí ibi gíga tí ó ti ṣe sí Beteli.

1 Kings 12:32 in English

1 Kings 12:32 · Berean Standard Bible

And Jeroboam ordained a feast on the fifteenth day of the eighth month,* like the feast that was in Judah, and he offered sacrifices on the altar; he made this offering in Bethel to sacrifice to the calves he had set up, and he installed priests in Bethel for the high places he had set up.

Context

30Nǹkan yìí sì di ẹ̀ṣẹ̀; àwọn ènìyàn sì lọ títí dé Dani láti sin èyí tí ó wà níbẹ̀. 31Jeroboamu sì kọ́ ojúbọ sórí ibi gíga, ó sì yan àwọn àlùfáà láti inú àwọn ènìyàn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe inú àwọn ọmọ Lefi. 32Jeroboamu sì dá àsè sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kẹjọ gẹ́gẹ́ bí àsè tí ó wà ní Juda, ó sì rú ẹbọ lórí pẹpẹ. Ó ṣe èyí ní Beteli, ó rú ẹbọ sí àwọn ọmọ màlúù tí ó ṣe. Ó sì fi àwọn àlùfáà sí ibi gíga tí ó ti ṣe sí Beteli. 33Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kẹjọ, oṣù tí ó rò ní ọkàn ara rẹ̀, ó sì rú ẹbọ lórí pẹpẹ tí ó kọ́ ní Beteli. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì dá àsè sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli, ó sì gun orí pẹpẹ náà lọ láti rú ẹbọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.