Native Bible

1 Kings 10:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí ayaba Ṣeba sì rí gbogbo ọgbọ́n Solomoni àti ààfin tí ó ti kọ́.

1 Kings 10:4 in English

1 Kings 10:4 · Berean Standard Bible

When the queen of Sheba saw all the wisdom of Solomon, the palace he had built,

Context

2Ó sì wá sí Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹgbẹ́ èrò ńlá ńlá, pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà, àti òkúta iyebíye, ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sì bá a sọ gbogbo èyí tí ń bẹ ní ọkàn rẹ̀. 3Solomoni sì dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyí tí ó ṣòro fún ọba láti ṣàlàyé fún un. 4Nígbà tí ayaba Ṣeba sì rí gbogbo ọgbọ́n Solomoni àti ààfin tí ó ti kọ́. 5Oúnjẹ tí ó wà lórí i tábìlì rẹ̀, ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti ìdúró àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ìwọṣọ wọn, àwọn agbọ́tí rẹ̀, àti ẹbọ sísun tí ó sun ní ilé Olúwa, kò sì sí ẹ̀mí kan nínú rẹ̀ mọ́! 6Ó sì wí fún ọba pé, “Òtítọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní orílẹ̀-èdè mi ní ti iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.