Native Bible

1 Kings 10:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Solomoni sì dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyí tí ó ṣòro fún ọba láti ṣàlàyé fún un.

1 Kings 10:3 in English

1 Kings 10:3 · Berean Standard Bible

And Solomon answered all her questions; nothing was too difficult for the king to explain.

Context

1Nígbà tí ayaba Ṣeba gbọ́ òkìkí Solomoni àti ì bà ṣe pọ̀ rẹ̀ ní ti orúkọ Olúwa, ó sì wá láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè líle. 2Ó sì wá sí Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹgbẹ́ èrò ńlá ńlá, pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà, àti òkúta iyebíye, ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sì bá a sọ gbogbo èyí tí ń bẹ ní ọkàn rẹ̀. 3Solomoni sì dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyí tí ó ṣòro fún ọba láti ṣàlàyé fún un. 4Nígbà tí ayaba Ṣeba sì rí gbogbo ọgbọ́n Solomoni àti ààfin tí ó ti kọ́. 5Oúnjẹ tí ó wà lórí i tábìlì rẹ̀, ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti ìdúró àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ìwọṣọ wọn, àwọn agbọ́tí rẹ̀, àti ẹbọ sísun tí ó sun ní ilé Olúwa, kò sì sí ẹ̀mí kan nínú rẹ̀ mọ́!

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.