1 Ọba 10:2
1 Kings 10:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì wá sí Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹgbẹ́ èrò ńlá ńlá, pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà, àti òkúta iyebíye, ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sì bá a sọ gbogbo èyí tí ń bẹ ní ọkàn rẹ̀.
1 Kings 10:2 in English
1 Kings 10:2 · Berean Standard Bible
She arrived in Jerusalem with a very large caravan—with camels bearing spices, gold in great abundance, and precious stones. So she came to Solomon and spoke to him all that was on her mind.
Context
1Nígbà tí ayaba Ṣeba gbọ́ òkìkí Solomoni àti ì bà ṣe pọ̀ rẹ̀ ní ti orúkọ Olúwa, ó sì wá láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè líle. 2Ó sì wá sí Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹgbẹ́ èrò ńlá ńlá, pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà, àti òkúta iyebíye, ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sì bá a sọ gbogbo èyí tí ń bẹ ní ọkàn rẹ̀. 3Solomoni sì dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyí tí ó ṣòro fún ọba láti ṣàlàyé fún un. 4Nígbà tí ayaba Ṣeba sì rí gbogbo ọgbọ́n Solomoni àti ààfin tí ó ti kọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.