1 Kọrinti 7:12
1 Corinthians 7:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo fẹ́ fi àwọn ìmọ̀ràn kan kún ún fún un yín, kì í ṣe àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Bí arákùnrin bá fẹ́ aya tí kò gbàgbọ́, tí aya náà sá á fẹ́ dúró tí ọkọ náà, ọkọ náà tí í ṣe onígbàgbọ́ kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
1 Corinthians 7:12 in English
1 Corinthians 7:12 · Berean Standard Bible
To the rest I say this (I, not the Lord): If a brother has an unbelieving wife and she is willing to live with him, he must not divorce her.
Context
10Àwọn ti ó ti gbéyàwó àti àwọn tí ó lọ́kọ, ni mo fẹ́ pa á láṣẹ fún kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ mi ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa: “Obìnrin kò gbọdọ̀ kọ́ fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.” 11Ṣùgbọ́n tí ó bá fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀; jẹ́ kí ó wà láìní ọkọ mọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó bá ọkọ rẹ̀ làjà, kí ọkọ kí ó má ṣe aya rẹ̀ sílẹ̀. 12Mo fẹ́ fi àwọn ìmọ̀ràn kan kún ún fún un yín, kì í ṣe àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Bí arákùnrin bá fẹ́ aya tí kò gbàgbọ́, tí aya náà sá á fẹ́ dúró tí ọkọ náà, ọkọ náà tí í ṣe onígbàgbọ́ kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 13Tí ó bá sì jẹ́ obìnrin ló fẹ́ ọkọ tí kò gbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí ọkọ náà ń fẹ́ kí obìnrin yìí dúró tí òun, aya náà kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 14Nítorí pé ó ṣe é ṣe kí a lè mú ọkọ tí kò gba Kristi gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa aya tí í ṣe onígbàgbọ́, a sì le mú ìyàwó tí kò gba Kristi gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ wọn yóò jẹ́ aláìmọ́. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá kọ ara wọn sílẹ̀, ó ṣe é ṣe kí àwọn ọmọ wọn di mímọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.