Native Bible

1 Corinthians 7:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Tí ó bá sì jẹ́ obìnrin ló fẹ́ ọkọ tí kò gbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí ọkọ náà ń fẹ́ kí obìnrin yìí dúró tí òun, aya náà kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

1 Corinthians 7:13 in English

1 Corinthians 7:13 · Berean Standard Bible

And if a woman has an unbelieving husband and he is willing to live with her, she must not divorce him.

Context

11Ṣùgbọ́n tí ó bá fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀; jẹ́ kí ó wà láìní ọkọ mọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó bá ọkọ rẹ̀ làjà, kí ọkọ kí ó má ṣe aya rẹ̀ sílẹ̀. 12Mo fẹ́ fi àwọn ìmọ̀ràn kan kún ún fún un yín, kì í ṣe àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Bí arákùnrin bá fẹ́ aya tí kò gbàgbọ́, tí aya náà sá á fẹ́ dúró tí ọkọ náà, ọkọ náà tí í ṣe onígbàgbọ́ kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 13Tí ó bá sì jẹ́ obìnrin ló fẹ́ ọkọ tí kò gbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí ọkọ náà ń fẹ́ kí obìnrin yìí dúró tí òun, aya náà kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 14Nítorí pé ó ṣe é ṣe kí a lè mú ọkọ tí kò gba Kristi gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa aya tí í ṣe onígbàgbọ́, a sì le mú ìyàwó tí kò gba Kristi gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ wọn yóò jẹ́ aláìmọ́. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá kọ ara wọn sílẹ̀, ó ṣe é ṣe kí àwọn ọmọ wọn di mímọ́. 15Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin tí i ṣe aláìgbàgbọ́ náà bá fẹ́ láti lọ, jẹ́ kí ó máa lọ. Arákùnrin tàbí arábìnrin náà kò sí lábẹ́ ìdè mọ́; Ọlọ́run ti pè wá láti gbé ní àlàáfíà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.