Native Bible

1 Corinthians 7:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ti ó ti gbéyàwó àti àwọn tí ó lọ́kọ, ni mo fẹ́ pa á láṣẹ fún kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ mi ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa: “Obìnrin kò gbọdọ̀ kọ́ fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.”

1 Corinthians 7:10 in English

1 Corinthians 7:10 · Berean Standard Bible

To the married I give this command (not I, but the Lord): A wife must not separate from her husband.

Context

8Nítorí náà, mo wí fún àwọn àpọ́n àti opó pé, ó sàn kí wọ́n kúkú wà gẹ́gẹ́ bí èmi tí wà. 9Ṣùgbọ́n bí wọ́n kò bá lè mú ara dúró, kí wọ́n gbéyàwó tàbí kí wọ́n fẹ́ ọkọ, nítorí pé ó sàn láti gbéyàwó jù láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lọ. 10Àwọn ti ó ti gbéyàwó àti àwọn tí ó lọ́kọ, ni mo fẹ́ pa á láṣẹ fún kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ mi ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa: “Obìnrin kò gbọdọ̀ kọ́ fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.” 11Ṣùgbọ́n tí ó bá fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀; jẹ́ kí ó wà láìní ọkọ mọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó bá ọkọ rẹ̀ làjà, kí ọkọ kí ó má ṣe aya rẹ̀ sílẹ̀. 12Mo fẹ́ fi àwọn ìmọ̀ràn kan kún ún fún un yín, kì í ṣe àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Bí arákùnrin bá fẹ́ aya tí kò gbàgbọ́, tí aya náà sá á fẹ́ dúró tí ọkọ náà, ọkọ náà tí í ṣe onígbàgbọ́ kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.