1 Kọrinti 4:8
1 Corinthians 4:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ni báyìí ẹ ní ohun gbogbo tí ẹ ń fẹ́! Báyìí ẹ sì ti di ọlọ́rọ̀! Ẹ ti di ọba. Lójú yín, àwa ti di ẹni ẹ̀yìn. Ìbá dùn mọ́ mi tí ó bá jẹ́ pé lóòtítọ́ ni ẹ ti di ọba lórí ìtẹ́ yín: tí a ó sì máa jẹ ọba pẹ̀lú yín!
1 Corinthians 4:8 in English
1 Corinthians 4:8 · Berean Standard Bible
Already you have all you want. Already you have become rich. Without us, you have become kings. How I wish you really were kings, so that we might be kings with you!
Context
6Ẹ kíyèsi i pé, mo ti fi ara mi àti Apollo ṣe àpẹẹrẹ nǹkan tí mo wí, pé kí ẹ̀yin lè ti ipa wa kọ́ láti máa ṣe ohun tí a ti kọ̀wé kọjá. “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe tìtorí ẹnìkan gbéraga sí ẹnìkejì.” 7Nítorí ta ni ó mú ọ yàtọ̀ sí àwọn ẹlòmíràn? Kí ni ìwọ ni tí ìwọ kò rí gbà? Tí ìwọ ba sì gbà á, èétiṣe tí ìwọ fi ń halẹ̀ bí ẹni pé ìwọ kò gba á? 8Ni báyìí ẹ ní ohun gbogbo tí ẹ ń fẹ́! Báyìí ẹ sì ti di ọlọ́rọ̀! Ẹ ti di ọba. Lójú yín, àwa ti di ẹni ẹ̀yìn. Ìbá dùn mọ́ mi tí ó bá jẹ́ pé lóòtítọ́ ni ẹ ti di ọba lórí ìtẹ́ yín: tí a ó sì máa jẹ ọba pẹ̀lú yín! 9Nítorí mo rò pé Ọlọ́run ń fi àwa aposteli hàn ní ìkẹyìn bí ẹni tí a dá lẹ́bi ikú bí àwọn, nítorí tí a fi wá ṣe ìran wò fún àwọn ènìyàn àti àwọn angẹli àti gbogbo ayé. 10Àwa jẹ́ aṣiwèrè nítorí Kristi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ọlọ́gbọ́n nínú Kristi! Àwa jẹ́ aláìlera, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ alágbára! Ẹ̀yin jẹ́ ẹni àyẹ́sí, àwa jẹ ẹni ẹ̀gàn!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.