Native Bible

1 Corinthians 4:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí mo rò pé Ọlọ́run ń fi àwa aposteli hàn ní ìkẹyìn bí ẹni tí a dá lẹ́bi ikú bí àwọn, nítorí tí a fi wá ṣe ìran wò fún àwọn ènìyàn àti àwọn angẹli àti gbogbo ayé.

1 Corinthians 4:9 in English

1 Corinthians 4:9 · Berean Standard Bible

For it seems to me that God has displayed us apostles at the end of the procession, like prisoners appointed for death. We have become a spectacle to the whole world, to angels as well as to men.

Context

7Nítorí ta ni ó mú ọ yàtọ̀ sí àwọn ẹlòmíràn? Kí ni ìwọ ni tí ìwọ kò rí gbà? Tí ìwọ ba sì gbà á, èétiṣe tí ìwọ fi ń halẹ̀ bí ẹni pé ìwọ kò gba á? 8Ni báyìí ẹ ní ohun gbogbo tí ẹ ń fẹ́! Báyìí ẹ sì ti di ọlọ́rọ̀! Ẹ ti di ọba. Lójú yín, àwa ti di ẹni ẹ̀yìn. Ìbá dùn mọ́ mi tí ó bá jẹ́ pé lóòtítọ́ ni ẹ ti di ọba lórí ìtẹ́ yín: tí a ó sì máa jẹ ọba pẹ̀lú yín! 9Nítorí mo rò pé Ọlọ́run ń fi àwa aposteli hàn ní ìkẹyìn bí ẹni tí a dá lẹ́bi ikú bí àwọn, nítorí tí a fi wá ṣe ìran wò fún àwọn ènìyàn àti àwọn angẹli àti gbogbo ayé. 10Àwa jẹ́ aṣiwèrè nítorí Kristi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ọlọ́gbọ́n nínú Kristi! Àwa jẹ́ aláìlera, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ alágbára! Ẹ̀yin jẹ́ ẹni àyẹ́sí, àwa jẹ ẹni ẹ̀gàn! 11Títí di wákàtí yìí ni a ń rìn kiri nínú ebi àti òǹgbẹ, a n wọ aṣọ àkísà, tí a sì ń lù wa, tí a kò sì ní ibùgbé kan.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.