1 Kọrinti 4:18
1 Corinthians 4:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo mọ̀ pé àwọn mìíràn nínú yín tó ya onígbèéraga ènìyàn, tí wọn ń rò pé ẹ̀rù ń bà mi láti wá sọ́dọ̀ yín.
1 Corinthians 4:18 in English
1 Corinthians 4:18 · Berean Standard Bible
Some of you have become arrogant, as if I were not coming to you.
Context
16Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ máa ṣe àfarawé mi. 17Nítorí náà ni mo ṣe rán Timotiu sí i yín, ẹni tí í ṣe ọmọ mi olùfẹ́ àti olódodo nínú Olúwa, ẹni tí yóò máa mú yín rántí ọ̀nà mi tí ó wà nínú Kristi Jesu, gẹ́gẹ́ bí mo ti ń kọ́ni nínú gbogbo ìjọ níbi gbogbo. 18Mo mọ̀ pé àwọn mìíràn nínú yín tó ya onígbèéraga ènìyàn, tí wọn ń rò pé ẹ̀rù ń bà mi láti wá sọ́dọ̀ yín. 19Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ̀ yín wá ní àìpẹ́ yìí bí Olúwa bá fẹ́; èmi yóò ṣe ìwádìí bí àwọn agbéraga yìí ṣe ń sọ̀rọ̀ àti agbára tí wọ́n ní. 20Nítorí ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe nínú ọ̀rọ̀, bí kò ṣe nínú agbára.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.