1 Kọrinti 14:4
1 Corinthians 14:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ ń fi ẹsẹ̀ ara rẹ̀ mulẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni ti ń sọtẹ́lẹ̀ ń fi ẹsẹ̀ ìjọ múlẹ̀.
1 Corinthians 14:4 in English
1 Corinthians 14:4 · Berean Standard Bible
The one who speaks in a tongue edifies himself, but the one who prophesies edifies the church.
Context
2Nítorí ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, kò bá ènìyàn sọ̀rọ̀ bì ko ṣe Ọlọ́run: nítorí kó sí ẹni tí ó gbọ́; ṣùgbọ́n nípá ti Ẹ̀mí ó ń sọ ohun ìjìnlẹ̀. 3Ṣùgbọ́n ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ ń ba àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ìmúdúró, àti ìgbaniníyànjú, àti ìtùnú. 4Ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ ń fi ẹsẹ̀ ara rẹ̀ mulẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni ti ń sọtẹ́lẹ̀ ń fi ẹsẹ̀ ìjọ múlẹ̀. 5Ṣùgbọ́n ìbá wù mí ki gbogbo yín lè máa sọ onírúurú èdè, ṣùgbọ́n kí ẹ kúkú máa sọtẹ́lẹ̀, ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ pọ̀ jú ẹni ti ń fèdèfọ̀ lọ, bi kọ ṣe pé ó bá ń ṣe ìtumọ̀, kí ìjọ bá à lè kọ́ ẹ̀kọ́. 6Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ará, bí mo bá wá sí àárín yín, tí mo sì ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, èrè kín ni èmi yóò jẹ́ fún yin, bi ko ṣe pé mo bá ń bá yín sọ̀rọ̀, yálà nípa ìṣípayá, tàbí ìmọ̀ tàbí nípá ìsọtẹ́lẹ̀, tàbí nípa ẹ̀kọ́?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.