1 Kọrinti 14:5
1 Corinthians 14:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ìbá wù mí ki gbogbo yín lè máa sọ onírúurú èdè, ṣùgbọ́n kí ẹ kúkú máa sọtẹ́lẹ̀, ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ pọ̀ jú ẹni ti ń fèdèfọ̀ lọ, bi kọ ṣe pé ó bá ń ṣe ìtumọ̀, kí ìjọ bá à lè kọ́ ẹ̀kọ́.
1 Corinthians 14:5 in English
1 Corinthians 14:5 · Berean Standard Bible
I wish that all of you could speak in tongues, but I would rather have you prophesy. He who prophesies is greater than one who speaks in tongues, unless he interprets so that the church may be edified.
Context
3Ṣùgbọ́n ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ ń ba àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ìmúdúró, àti ìgbaniníyànjú, àti ìtùnú. 4Ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ ń fi ẹsẹ̀ ara rẹ̀ mulẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni ti ń sọtẹ́lẹ̀ ń fi ẹsẹ̀ ìjọ múlẹ̀. 5Ṣùgbọ́n ìbá wù mí ki gbogbo yín lè máa sọ onírúurú èdè, ṣùgbọ́n kí ẹ kúkú máa sọtẹ́lẹ̀, ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ pọ̀ jú ẹni ti ń fèdèfọ̀ lọ, bi kọ ṣe pé ó bá ń ṣe ìtumọ̀, kí ìjọ bá à lè kọ́ ẹ̀kọ́. 6Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ará, bí mo bá wá sí àárín yín, tí mo sì ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, èrè kín ni èmi yóò jẹ́ fún yin, bi ko ṣe pé mo bá ń bá yín sọ̀rọ̀, yálà nípa ìṣípayá, tàbí ìmọ̀ tàbí nípá ìsọtẹ́lẹ̀, tàbí nípa ẹ̀kọ́? 7Bẹ́ẹ̀ ní pẹ̀lú àwọn nǹkan tí kò ní ẹ̀mí tí ń dún, ìbá à ṣe fèrè tàbí dùùrù bí kò ṣe pé ìyàtọ̀ bá wà nínú wọn, a ó tí ṣe mọ ohùn tí fèrè tàbí tí dùùrù ń wí?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.