Native Bible

1 Corinthians 12:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí etí bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ojú, èmi kì í ṣe apá kan ara,” èyí kò le mú kí ó má jẹ́ apá kan ara mọ́.

1 Corinthians 12:16 in English

1 Corinthians 12:16 · Berean Standard Bible

And if the ear should say, “Because I am not an eye, I do not belong to the body,” that would not make it any less a part of the body.

Context

14Bẹ́ẹ̀ ni, ara, kì í ṣe ẹ̀yà kan ṣoṣo bí kò ṣe púpọ̀. 15Tí ẹsẹ̀ bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ọwọ́, èmi kì í ṣe ti ara,” èyí kò wí pé kì í ṣe ọ̀kan lára nínú ẹ̀yà ara. 16Bí etí bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ojú, èmi kì í ṣe apá kan ara,” èyí kò le mú kí ó má jẹ́ apá kan ara mọ́. 17Bí gbogbo ara bá jẹ́ ojú, níbo ni ìgbọ́ran ìbá gbé wà? Bí gbogbo ara bá jẹ́ etí, níbo ni ìgbóórùn ìbá gbé wà? 18Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi àwọn ẹ̀yà ara si ara wa, ó sí fi ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan sí ibi tí ó fẹ́ kí ó wà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.