Native Bible

1 Corinthians 12:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni, ara, kì í ṣe ẹ̀yà kan ṣoṣo bí kò ṣe púpọ̀.

1 Corinthians 12:14 in English

1 Corinthians 12:14 · Berean Standard Bible

For the body does not consist of one part, but of many.

Context

12Ara jẹ́ ọ̀kan tí ó ní àwọn ẹ̀yà púpọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹ̀yà ara tí ó pọ̀ wọ̀nyí ni ó papọ̀ láti jẹ́ ara kan ṣoṣo. Bákan náà ni ó rí pẹ̀lú ara Kristi tí í ṣe ìjọ. 13Nítorí pé nínú Ẹ̀mí kan ní a ti bamitiisi gbogbo wa sínú ara kan, ìbá à ṣe Júù, ìbá à ṣe Giriki, ìbá à ṣe ẹrú, ìbá à ṣe òmìnira, gbogbo wa ni a mu nínú Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà. 14Bẹ́ẹ̀ ni, ara, kì í ṣe ẹ̀yà kan ṣoṣo bí kò ṣe púpọ̀. 15Tí ẹsẹ̀ bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ọwọ́, èmi kì í ṣe ti ara,” èyí kò wí pé kì í ṣe ọ̀kan lára nínú ẹ̀yà ara. 16Bí etí bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ojú, èmi kì í ṣe apá kan ara,” èyí kò le mú kí ó má jẹ́ apá kan ara mọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.