1 Kọrinti 12:13
1 Corinthians 12:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé nínú Ẹ̀mí kan ní a ti bamitiisi gbogbo wa sínú ara kan, ìbá à ṣe Júù, ìbá à ṣe Giriki, ìbá à ṣe ẹrú, ìbá à ṣe òmìnira, gbogbo wa ni a mu nínú Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà.
1 Corinthians 12:13 in English
1 Corinthians 12:13 · Berean Standard Bible
For in one Spirit we were all baptized into one body, whether Jews or Greeks, slave or free, and we were all given one Spirit to drink.
Context
11Àní, Ẹ̀mí kan ṣoṣo ní ń fún ni ní gbogbo ẹ̀bùn àti agbára wọ̀nyí. Òun ni ẹni tí ń ṣe ìpinnu ẹ̀bùn tí ó yẹ láti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan. 12Ara jẹ́ ọ̀kan tí ó ní àwọn ẹ̀yà púpọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹ̀yà ara tí ó pọ̀ wọ̀nyí ni ó papọ̀ láti jẹ́ ara kan ṣoṣo. Bákan náà ni ó rí pẹ̀lú ara Kristi tí í ṣe ìjọ. 13Nítorí pé nínú Ẹ̀mí kan ní a ti bamitiisi gbogbo wa sínú ara kan, ìbá à ṣe Júù, ìbá à ṣe Giriki, ìbá à ṣe ẹrú, ìbá à ṣe òmìnira, gbogbo wa ni a mu nínú Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà. 14Bẹ́ẹ̀ ni, ara, kì í ṣe ẹ̀yà kan ṣoṣo bí kò ṣe púpọ̀. 15Tí ẹsẹ̀ bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ọwọ́, èmi kì í ṣe ti ara,” èyí kò wí pé kì í ṣe ọ̀kan lára nínú ẹ̀yà ara.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.