1 Kọrinti 12:11
1 Corinthians 12:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àní, Ẹ̀mí kan ṣoṣo ní ń fún ni ní gbogbo ẹ̀bùn àti agbára wọ̀nyí. Òun ni ẹni tí ń ṣe ìpinnu ẹ̀bùn tí ó yẹ láti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan.
1 Corinthians 12:11 in English
1 Corinthians 12:11 · Berean Standard Bible
All these are the work of one and the same Spirit, who apportions them to each one as He determines.
Context
9Ó fi ẹ̀bùn ìgbàgbọ́ fún ẹlòmíràn, ẹlòmíràn ló sì fi agbára ìwòsàn fún nípa Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà. 10Ó fi agbára fún àwọn mìíràn láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu. Ó fún àwọn mìíràn lágbára láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ àti láti wàásù pẹ̀lú ìmísí. Bákan náà ló fún àwọn kan lẹ́bùn láti mọ ìyàtọ̀ láàrín àwọn ẹ̀mí. Ó fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn àti agbára láti lè sọ èdè tí wọn kò mọ̀. Bákan náà ó fún àwọn ẹlòmíràn lágbára láti mọ̀ àti láti túmọ̀ èdè tí wọn kò gbọ́ rí. 11Àní, Ẹ̀mí kan ṣoṣo ní ń fún ni ní gbogbo ẹ̀bùn àti agbára wọ̀nyí. Òun ni ẹni tí ń ṣe ìpinnu ẹ̀bùn tí ó yẹ láti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan. 12Ara jẹ́ ọ̀kan tí ó ní àwọn ẹ̀yà púpọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹ̀yà ara tí ó pọ̀ wọ̀nyí ni ó papọ̀ láti jẹ́ ara kan ṣoṣo. Bákan náà ni ó rí pẹ̀lú ara Kristi tí í ṣe ìjọ. 13Nítorí pé nínú Ẹ̀mí kan ní a ti bamitiisi gbogbo wa sínú ara kan, ìbá à ṣe Júù, ìbá à ṣe Giriki, ìbá à ṣe ẹrú, ìbá à ṣe òmìnira, gbogbo wa ni a mu nínú Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.