1 Kọrinti 10:12
1 Corinthians 10:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, ẹni tí ó bá rò pé òun dúró, kí ó kíyèsára kí ó ma ba à ṣubú.
1 Corinthians 10:12 in English
1 Corinthians 10:12 · Berean Standard Bible
So the one who thinks he is standing firm should be careful not to fall.
Context
10Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó má ṣe kùn, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọ́n ṣe kùn, tí a sì ti ọwọ́ olùparun run wọ́n. 11Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí wọn bí àpẹẹrẹ fún wa, a sì kọ̀wé wọn fún ìkìlọ̀ fún wa, àwa ẹni tí ìgbẹ̀yìn ayé dé bá. 12Nítorí náà, ẹni tí ó bá rò pé òun dúró, kí ó kíyèsára kí ó ma ba à ṣubú. 13Kò sí ìdánwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó mọ níwọ̀n fún ènìyàn, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlọ́run, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ́n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ̀yin ba à lè faradà á. 14Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.